Matteu 28:18-20; 9:38

Lesson 365 - Junior

Memory Verse
“Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wò oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikoré na” (Johannu 4:35).
Notes

“Jesu fẹran awọn ọmọde,

Oun ni olutọju gbogbo awọn ọmọde;

Pupa ati ofefe, dudu ati funfun,

Gbogbo wọn ṣọwọn loju Rè̩:

Jesu fẹran awọn ọmọde nibigbogbo.”

Awa ti a n lọ si Ile-è̩kọỌjọ-Isinmi ni ọjọjọỌsẹ le ṣalai mọ pe ẹgbẹgbẹrun aimoye awọn ọmọde ni o wa kaakiri aye ti wọn ko i ti gbọ nipa Jesu ri. Kò si Ile-è̩kọỌjọ Isinmi ti wọn le lọ, kò si ẹniti o ti I sọ fun wọn pe Jesu ku lati gba awọn ẹlẹṣẹ là ati pe Oun n fẹ ki wọn ba Oun gbe ni Ọrun. Wọn wà ninu okunkun, wọn nduro de ki Imọlẹ Ihinrere tan sori wọn. Ọpọlọpọ ni yoo ku ti yoo si ṣegbe. Awa o ha ti ṣe le duro niwaju Ọlọrun lailẹbi, bi a ba kuna lati sọ fun wọn nipa Jesu!

Nigbati O ku saa diẹ ki Jesu lọ si Ọrun, O pe awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ jọ O si sọ iṣẹ ti wọn o ṣe fun wọn. “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmo, ati ni ti Ẹmi Mimọ: ki ẹ ma kọ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi I, emi à pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye” (Matteu 28:19, 20).

Ọpọlọpọ awọn ajihinrere ni o ti lọ si ilẹ ajeji lati sọ fun awọn ti ko ni imọ otitọ nipa Jesu, bẹẹni a si ti túmọ iwe-itankalẹ Ihinrere si ọpọlọpọ ede a si n fi wọn ranṣẹ si ọpọlọpọ orilẹ-ede agbaye; ṣugbọn a ṣirò rè̩ pe bi a ba pin aye si ọna mẹta apa meji ni kò i ti gbọ nipa Jesu. Awa ha n gbiyanju lati pa aṣẹ Jesu mọ ti o wipe, “Ẹ lọ si gbogbo aiye”?

Agbara fun Iṣẹ

Nigbati Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe ki wọn duro ni Jerusalẹmu titi a o fi fi Ẹmi Mimọ wọ wọn, O wi fun wọn pe wọn o gba agbara lati ṣe ẹlẹri fun Oun “titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Ohun ti wọn o ri gba yoo fun wọn ni agbara lati sọ itan Jesu fun ọpọlọpọ eniyan ti o jina rere si Jerusalẹmu.

Inunibini

Awọn ipade iyanu ni o tẹle Ọjọ Pẹntekọsti, Nigbati ọgọfa ọmọ-ẹhin gba agbara Ẹmi Mimọ. Peteru di oniwasu nla lẹsẹkẹsẹ, ẹgbẹdogun (3000) eniyan si yipada ni ọjọ kan. Awọn ọmọ-ẹhin ngbadun itujade Ẹmi MimọỌlọrun, laisi aniani gbogbo awọn Onigbagbọ ni iba ni inudidun lati duro ni Jerusalẹmu fun ọpọ ibukun si i. S̩ugbọn Jesu wipe, “lọ.”

Awọn ọmọ-ẹhin le ṣalai mọ pe akoko ti to lati lọ, ṣugbọn nigbati awọn Farisi bẹrẹsi fi awọn eniyan sinu tubu, ti wọn si npa wọn nigbamiran, nitoripe wọn gba Jesu gbọ, wọn tukakiri si ọpọlọpọ ilu ti o yi Jerusalẹmu ka. “Nwọn si jade lọ, nwọn si nwasu nibigbogbo, Oluwa si mba wọn ṣiṣẹ, o si n fi idi ọrọ na kalẹ, nipa ami ti ntẹle e” (Marku 16:20). Jesu ti sọ pe Oun o ba wọn lọ, O si ṣe bẹẹ.

Ipe si Ilẹ-awọn-alawọ-funfun

Lẹhin ti Paulu Apọsteli yipada o lọ si irin-ajo ti itankalẹ Ihinrere nigba mẹta. Ibikibi ti o de ni o n sọ fun awọn eniyan nipa Jesu. L’oru ọjọ kan nigbati o wa ni Troasi, ninu iran o ri okunrin Makedonia kan ti n wipe, “Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 16:9). Paulu mọ lesẹkanna pe ipe lati ọdọ Oluwa ni, oun ati awọn oluranlọwọ rè̩ ko jafara lati lọ si Makedonia. Eyi ni ibẹrẹ iwasu Ihinrere ni Ilẹ awọn alawọ funfun.

Ọpọlọpọ eniyan ni a gbala nipasẹ iwasu wọn, ṣugbọn ki I ṣe gbogbo eniyan ni o gba ohun ti wọn sọ. Awọn miran kun fun irunu tobẹẹ ti wọn fi Paulu ati Sila sinu tubu, ṣugbọn eyini kọ da iwasu wọn duro. Ọlọrun ti ran wọn lati lọ wasu fun awọn eniyan ti kò mọ nipa Jesu, wọn si ṣe eyiti wọn le ṣe lati sọ ti Ihinrere naa, laika iya ti wọn yoo farada si.

Sisẹ ara ẹni

Iyọọda aa-ẹni jẹẹmi ajihinrere tootọ. O n fẹ lati jiya fun Jesu bi o ba yẹ bẹẹ. Ko bere fun ere aye kankan. “Lati ri ayọ igbala loju ọkàn kan ti a gbala to fun un ni itẹlọrun fun iṣẹ ti o ṣe.” O n fẹ lati fi ile rè̩ silẹ pẹlu gbogbo itura rè̩, awọn ọrẹ ati awọn ibatan rè̩ pẹlu, ki o si lọ si ibiti Ọlọrun pe e lati lọ.

Ki a to le jẹ ajihinrere ti yoo lérè fun Jesu, a nilati ri igbala (eyini ni pe ki a dari ẹṣẹ wa ji wa); ki a si sọ wa di mimọ (eyini ni pe ki a di ọlọkàn funfun) nipa isodimimọ. A nilati fi Ẹmi Mimọ wọni gẹghẹ bi awọn ọmọ-ẹhin ti gba agbara yi ni Ọjọ Pẹntekosti ki wọn to jade lọ lati jẹ ajihinrere.

Lẹhin eyi ẹni naa nilati ni ifẹ fun ẹmi awọn eniyan, ikaanu fun ọkàn ti o sọnu. Awọn ajihinrere ti o ti jade lọ ti wi bayi pe ifẹ tootọ fun awọn eniyan kòṣe igbe wọ. Eniyan le maa dibọn bi ẹnipe oun fẹran awọn ti o n ṣe iṣẹ-iranṣẹ fun, ṣugbọn awọn eniyan le mọ bi o ba jẹ pe lotitọ lati inu ọkàn rè̩ ni o ti n ṣe iṣẹ-iranṣẹ yi nitoripe o fẹran wọn gẹgẹ bi o ti fẹran ẹmi wọn, tabi oun nṣe e fun idi miran.

Ajihinrere nilati mọ pe awọn eniyan ti oun nwasu fun jẹọkunrin,, obinrin, ati awọn ọmọde ti Kristi kú fun. Jesu kò fẹ pe ki ẹnikan ni gbogbo agbaye ki o ṣegbe. O fi ẹmi Rè̩ lelẹ lati gba wa là, O si n fẹ ki awa naa fi aye wa lelẹ ninu iṣẹ-isin fun awọn ẹlomiran. A bukun wa ki a ba le jẹ ibukun fun awọn ẹlomiran. A nilati fẹẹ lati jiya pẹlu awọn ti a n ṣe aayan lati ran lọwọ. Eyini ko pọju fun wa lati ṣe..

Jẹsu fi Ile Rè̩ Iyanu nibiti gbogbo awọn angẹli ti n juba Rè̩ silẹ, O si wá si aye lati gbe igbesi aye irẹlkẹ, ki I ṣe ninu aafin pẹlu awọn ọba, tabi ninu ile nla pẹlu awọn ọlọrọ, ṣugbọn ninu awọn ile kekeke pẹlu awọn eniyan ti o n ṣiṣé̩, awọn apẹja, awọn ti eniyan nla aye kò kasi. Apẹrẹ wa ni I ṣe. O si ti pe wa lati tẹle Oun lẹhin.

Ọpọlọpọ ede

Nigbati awọn ajihinrere bè̩rẹ si lọ si ilẹ awọn keferi ni iwọn ọgọrun ọdun tabi jubẹẹlọ sẹhin, ti wọn ri ọpọlọpọ eniyan ti ède wọn ko i ti ni akọsilẹ wọn kò le ka Bibeli tabi iwe nipa ẹsin igbagbọ. Ajihinrere naa nilati maa gbe laarin awọn eniyan na titi oun yoo fi kọ ede wọn to eyiti yoo fi le ba wọn sọrọ. Lẹhin eyi yoo gbiyanju akọsilẹ awọn ọrọ naa ki ède na ba le ṣe kọsilẹ. Lẹhin eyi yoo tumọ Bibeli tabi apakan ninu rè̩ si ede ti oun ti ṣe akọsilẹ rè̩. Oun nilati tumọọrọ Bibeli nigba miran lati ba agbegbe wọn mu. Fun àpẹẹrẹ, kò si awọn agutan ni ilẹ Iceland. Awọn ara ilè̩ yi kò ni mọ aitumọ pipe Jesu ni Ọdọ-agutan Ọlọrun. Nitorina awọn otumọ iṣáaju lo “seali” (orukọẹja kan) dipo Ọdọ-agutan. Ọpọlọpọ seali ni o wà ninu omi ti o yi Iceland ká awọn ara ilẹ na si le mọ itumọ “Seali Ọlọrun.” Lẹhin eyi ajihinrere naa nilati kọ awọn eniyan na lati ka ỌrọỌlọrun. Ọran ti o n gba ọjọ pupọ, ti ki i si ya borọ ni; o gba ọpọlọpọọdun ti o kun fun akitiyan è̩kọ ati ọpọlọpọ adura pẹlu iranwọỌlọrun lati mu ki ède kan ṣe ikọ silẹ, ki a si fun awọn eniyan ti o ni ède naa ni ỌrọỌlọrun lati ka. Awọn ajihinrere wọn ṣe e nitoripe wọn fẹran ẹmi awon eniyan, wọn si n fẹ ki wọn mọọna iye ainipẹkun. Ọpọlọpọ orilẹ-ede pẹlu oriṣiriṣi ède ni wọn n ka ỌrọỌlọrun lode oni nitori ijolootọ awọn ajihinrere akọkọ. A le fi iwe-irohin Ihinrere ranṣẹ si wọn lati ṣe iranlọwọ fun wọṅ lati di Onigbagbọ nitoripe ẹnikan ti kọ wọn ni iwe-kika.

Iṣẹ na n tẹsiwaju. Lati ọdun de ọdun ni a n fi awọn ède titun kun awọn ti o wà tẹlẹ, bẹẹni a si ti tumọ gbogbo Bibeli si igba odin mẹta (197) ede. Ẹgbẹrun o le ọkan-dinlọgọta (1059) ède ni o ni Iwe kan tabi jubẹẹlọ ninu awọn iwe Bibeli. S̩ugbọn sibẹsibẹ a ṣiro rè̩ pe ẹẹdẹgbẹsan (1700) ède ni ko i ti ni ọrọ kanṣoṣo ninu Ọrọ Iwe Mimọ.

Awọn ajihinrere miran ti ni iwuwo lọkan wọn lati sọ fun awọn keferi nipa Jesu nipa ẹrọ ikọrin. Diẹ ninu awọn a ṣoju wọn ti jade lọ si awọn ilu ti o pamọ nibiti a ko i ti kọède wọn silẹ, tabi nibiti a ko i ti tumọ Bibeli si ède wọn, wọn si ti ri ẹnikan ti o le sọède ilẹ naa ti o si tun le sọ eyiti ajihinrere naa n sọ. Lẹhin eyi yoo tumọ orọ iwaasu Ihinrere sinu ẹrọ ti n gba ọrọ silẹ. Lati inu eyi ti a ti maa n ṣe ẹrọ ti o n tun ọrọ ti a ti gba silẹ sọ ranṣẹ si awọn ti ko i ti gbọ Ihinrere li ède wọn. Awọn ajihinrere miran a maa gbe ẹrọ ti o n tun ọrọ ti a ti gba silẹ sọ ti o ṣe gbe rìn lọwọ wọn a si maa fi ẹrọ yi sọrọ Ihinrere ti igbala kuro ninu è̩ṣẹ fun awọn ti o ti sọnu ti wọn kò ni oye yi tẹlẹri.

Ẹmi Nsọrọ

Ọnakọna ti o wu ki a gba lati sọ fun awọn eniyan nipa Jesu, Ẹmi Ọlọrun ni lati ba ọkan sọrọ ki ẹniti o n gbọọrọ naa ba le ri igbala. Ẹmi Ọlọrun kò wa ogbufọ. Ajihinrere kan le maa ba keferi kan ti kò mọwe gbadura, ki ẹnikeji má tilẹ gbọèd ẹnikeji rara, sibẹẸmi Ọlọrun le so ọkàn wọn pọ tobẹẹ ti wọn o fi ni alaafia ti Jesu n fi fun ni nigbati O ba dariji ẹlẹṣẹ ti o ronupiwada.

Iṣẹ Ajihinrere Ni Ile

Iṣẹ ajihinrere ti wa le bè̩rẹ lati inu ọgba ile wa. Aladugbo wa le maa reti pe ki ẹnikan wa sọ fun oun nipa Jesu. Yoo ha ti ri bi a ba kuna lati so fun un pe Jesu yoo gba a kuro ninu è̩ṣẹ rè̩, tobẹ ti yoo fi ṣegbe si ọrun apadi? Ẹ jẹ ki gbogbo wa gbadura tọkàntọkàn pe ki Ọlọrun fi ẹnikan han wa ti a o sọ fun nipa Jesu, ki a si pe e wa si ile-isin. Nigbati a ba ji, ẹ jẹ ki a sọ fun Jesu lati dari wa lọ sọdọẹnikan ti o n fẹ igbala ki O si ran wa lọwọ lati sọ ohun ti o tọ. Leke gbogbo rè̩, ẹ jẹ ki a gbé igbesi-aye wa lọna ti awọn eniyan yoo fi ri i pe ọmọỌlọrun ni awa i ṣe. A jẹ aṣoju Ijọba Ọrun. Awa ha n huwà gẹgẹ bi ọmọ-ibilẹỌrun?

Awọn ẹlomiran laarin wa le maa ro pe awọn ṣetan lati lọ si ilẹ ajeji lati fi aye wọn ṣe iranlọwọ fun awọn ẹlomiran ki wọn ba le ri igbala, ṣugbọn ọna kankan kòṣi silẹ. Kin ni a le ṣe? A le gbadura fun awọn ti wọn n jade lọ, a si le fi ninu owo wa silẹ lati ṣe iranlọwọ fun wọn, lati fi tè̩ Bibeli ati Iwe itankalẹ Ihinrere ni ède miran. Ọpọlọpọ awọn ọmọde ni wọn ni owo ninu apoti ifi owo pamọ si wọn fun awọn ajihinrere. Wọn fun awọn ọmọde ti o wà ni ilẹ miran nitoripe Jesu fẹran wọn, awọn si n fẹ ran wọn lọwọ lati ri igbala.

Adura wa nilati jẹ atọkanwa pẹlu ọkàn otitọ. Ki Ọlọrun ran wa lọwọ lati le sọkun lori awọn wọnni ti o sọnu, ki a si bẹỌlọrun pe ki o ran ẹnikan lati ran wọn lọwọ ki Jesu to de. Jẹ ki a gbadura pẹlu ẹmi aimọ-ti-ara-ẹni-nikan pe, “Emi ni yi, Oluwa; ran mi.”

Ọdọmọkunrin kan bẹrẹ si fi itara ṣiṣẹ lati mu ki awọn ọdọ iyoku le ni ifẹ si iṣẹ ajihinrere. O gbadura pe, “Emi ni yi, Oluwa ran arabinrin mi.” O ro pe iṣẹ ti oun n ṣe ni ile ti ṣe pataki ju eyiti oun le fi silẹ lọ. S̩ugbọn ko si ẹnikan ti o le yọọda lati jade lọ lati ṣe iṣẹ ajihinrere yi titi o fi di alẹọjọ kan ti oun tikararè̩ kigbe pe, “Emi ni yi, Oluwa; ran mi.” Lẹhin eyi awọn iyoku tẹle apẹẹrẹ rè̩ wọn si yọọda ara wọn lati lọ si ibikibi ti Oluwa ba fẹ lati ran wọn. O duro ti ifi-ara-ẹni-rubọ rè̩, nisisiyi o n ṣiṣẹ fun Ọlọrun ni India, o n sọ nipa Jesu fun awọn ọkàn ti o ti sọnu.

Atete Murasilẹ

Kò si ẹniti o kereju ninu wa lati pese ara wa silẹ fun iṣẹ ajihinrere. Lẹhin ti a ba ti ni iriri Onigbagbọ mẹtẹta ti a nilati ni, a le maa gbadura pe ki Ọlọrun ran wa lọwọ lati mọỌrọ Rè̩ si i, ki O si fun wa ni ọgbọn Rè̩, ki a ba le ni oye nipa awọn eniyan naa ti a ni iwuwo ọkan fun lati ran lọwọ. A le kọè̩kọ nipa aṣa ati ede ilu naa ti a ni lọkàn pe Ọlọrun n pe wa lati lọ. S̩ugbọn nigbagbogbo a nilati maa gbadura pe ki Ọlọrun ṣamọna wa. Ọpọlọpọ ni è̩kọ ti Ọlọrun yoo kọ wa bi akoko ti n lọ ati nipa iriri. Bi a ba ti n jọwọ ara wa fun Ọlọrun to, ti a si n jọwọ ara wa fun Un lati ṣe ohunkohun ti O fẹ ki a ṣe, bẹẹni yoo ti yá to fun Un lati pese wa silẹ fun iṣẹ yi.

“Nitorina ẹ gbadura si Oluwa ikore ki o le ran awọn alagbaṣe sinu ikore rḝ” (Matteu 9:38).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Awọn orilẹ-ede wo ni Jesu ran awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ si?

  2. 2 Nitori kin ni Jesu ṣe paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lati duro ni Jerusalẹmu?

  3. 3 Kin ni mu ki awọn ọmọ-ẹhin fi Jerusalẹmu silẹ?

  4. 4 Kin ni ipe Makedonia eyiti Paulu gbọ?

  5. 5 Sọ diẹ ninu awọn iwarere ti ajihinrere tootọ nilati ni?

  6. 6 Bawo ni ohun ti Jesu fifun wa ti pọ to?

  7. 7 Ọna wo ni pupọ ninu awọn keferi gba fi ri Bibeli?

  8. 8 Nibo ni iṣẹ ajihinrere wa ti le bẹrẹ?

  9. 9 Bawo ni a ti ṣe le ṣe iṣẹ ajihinrere ni ile?